عَنْ النَّوَّاسِ بْنِ سَمْعَانَ الْأَنْصَارِيِّ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«ضَرَبَ اللهُ مَثَلًا صِرَاطًا مُسْتَقِيمًا، وَعَلَى جَنْبَتَيْ الصِّرَاطِ سُورَانِ، فِيهِمَا أَبْوَابٌ مُفَتَّحَةٌ، وَعَلَى الْأَبْوَابِ سُتُورٌ مُرْخَاةٌ، وَعَلَى بَابِ الصِّرَاطِ دَاعٍ يَقُولُ: أَيُّهَا النَّاسُ، ادْخُلُوا الصِّرَاطَ جَمِيعًا، وَلَا تَتَعَرَّجُوا، وَدَاعٍ يَدْعُو مِنْ فَوْقِ الصِّرَاطِ، فَإِذَا أَرَادَ يَفْتَحُ شَيْئًا مِنْ تِلْكَ الْأَبْوَابِ، قَالَ: وَيْحَكَ لَا تَفْتَحْهُ، فَإِنَّكَ إِنْ تَفْتَحْهُ تَلِجْهُ، وَالصِّرَاطُ الْإِسْلَامُ، وَالسُّورَانِ: حُدُودُ اللهِ، وَالْأَبْوَابُ الْمُفَتَّحَةُ: مَحَارِمُ اللهِ، وَذَلِكَ الدَّاعِي عَلَى رَأْسِ الصِّرَاطِ: كِتَابُ اللهِ، وَالدَّاعِي مِنِ فَوْقَ الصِّرَاطِ: وَاعِظُ اللهِ فِي قَلْبِ كُلِّ مُسْلِمٍ».
[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [مسند أحمد: 17634]
المزيــد ...
Lati ọdọ An-Nawwaas ọmọ Sam’haan Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
“Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan, ti ògiri méjì wa ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa, ti àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣí silẹ wa nibẹ, ti àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà ti wọn dà wálẹ̀ si n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa, olupepe kan n bẹ ni ẹnu ọ̀nà ojú ọ̀nà naa ti n sọ pé: Ẹ̀yin èèyàn, gbogbo yin ẹ ko sínú ọ̀nà naa, ẹ má ṣe wọ́, ati olupepe kan ti n pepe lati òkè ọ̀nà naa, ti o ba ti wa fẹ ṣí nǹkan kan ninu awọn ojú ọ̀nà yẹn, o maa sọ pé: Káì, ma ṣi i, ti o ba fi le ṣi i wàá wọ̀ ọ́, ojú ọ̀nà naa ni Isilaamu, àwọn ògiri méjèèjì naa ni: Awọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ ni: Awọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, ẹni tí n pepe ni orí ojú ọ̀nà naa ni: Tira Ọlọhun, ẹni tí n pepe ni òkè ojú ọ̀nà naa ni: Oníwàásù Ọlọhun ninu ọkàn gbogbo Musulumi”.
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 17634]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe: Ọlọhun fi àkàwé lélẹ̀ fun Isilaamu pẹlu ojú ọ̀nà tààrà ti o tẹ́ ti kò wọ́, tí ògiri méjì n bẹ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa ti wọn rọkirika rẹ, àwọn méjèèjì náà ni àwọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ n bẹ láàrin ògiri méjì yii, àwọn naa ni àwọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa ti ko nii jẹ ki ẹni tí n kọjá ri ẹni tí ó wà ninu rẹ, olupepe kan si n bẹ ni ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà naa ti n dari àwọn èèyàn ti o si n sọ fún wọn pé: Ẹ maa rìn lọ lori ẹ láì fi si etí ati ẹ̀gbẹ́, olupepe yii ni tira Ọlọhun, olupepe mìíràn tun wa ni òkè ọ̀nà naa; olupepe yii, gbogbo igba ti ẹni tí n rìn ni oju ọna naa ba ti fẹ ṣi aṣọ ẹnu ọ̀nà yẹn díẹ̀, o maa jagbe mọ́ ọn, o maa wa sọ fún un pé: Ó ṣe fún ẹ, o ò gbọdọ ṣí i! Ti o ba ṣi i, waa wọ inú ẹ, o ò si nii ni ikapa lati kọ̀ fun ara rẹ lati má wọlé, olupepe yii ni oníwàásù Ọlọhun ninu ọkan gbogbo Musulumi.