عن أبي بَكرة رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«إِذَا الْتَقَى الْمُسْلِمَانِ بِسَيْفَيْهِمَا فَالْقَاتِلُ وَالْمَقْتُولُ فِي النَّارِ»، فَقُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ هَذَا الْقَاتِلُ، فَمَا بَالُ الْمَقْتُولِ؟ قَالَ: «إِنَّهُ كَانَ حَرِيصًا عَلَى قَتْلِ صَاحِبِهِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 31]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Bakrah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni”, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a gbọ ti ẹni tí o pa èèyàn, ẹni tí wọ́n pa wa nkọ? O sọ pé: “Oun naa fẹ́ pa ẹni keji rẹ ni”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 31]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Mùsùlùmí meji ba pade ara wọn pẹ̀lú idà, ti ìkíni kejì wọn n gbero lati pa ìkejì rẹ; ẹni tí ó pa èèyàn maa wọ iná; tori pe oun ni o pa ikeji rẹ tààrà, Ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n pa wa ru àwọn saabe lójú pe: Báwo ni o ṣe maa wọ ina? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé torí pé oun naa fẹ́ pa ìkejì rẹ ni, ko si si nǹkan ti o kọ̀ fun un lati ma pa a ju pe ọwọ́ ẹni tí o pa a yá ju tiẹ̀ lọ ni.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìní-ẹ̀tọ́ si ìyà ẹni ti o ba pinnu láti da ẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn rẹ ti o si ṣe àwọn okùnfà rẹ tààrà.
  2. Ikilọ ti o lágbára kúrò nibi ki awọn Mùsùlùmí maa ba ara wọn ja, ati àdéhùn ìyà iná lori ẹ.
  3. Ìjà láàárín àwọn Musulumi pẹlu ẹ̀tọ́ kò kó sínú adehun ìyà naa, gẹgẹ bii bíbá àwọn ti o kọjá ẹnu-ala jà ati awọn obilẹjẹ.
  4. Ẹni ti o ba da ẹṣẹ ńlá ko nii di Kèfèrí pẹlu ọ̀wọ́ pé ó kàn dá ẹṣẹ naa; torí pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe àwọn ti wọn n ba ara wọn jà ni Musulumi.
  5. Ti Musulumi meji ba pade ara wọn pẹ̀lú èyíkéyìí nǹkan ti wọn le fi pa èèyàn, ti ọkan ninu wọn wa pa ikeji, ẹni ti o pa èèyàn ati ẹni tí wọ́n pa maa wọ ina, wọn kan dárúkọ idà ninu hadiisi naa lati fi ṣe àpèjúwe ni.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)