عَنْ أَبِي ذَرٍّ، جُنْدُبِ بْنِ جُنَادَةَ، وَأَبِي عَبْدِ الرَّحْمَنِ، مُعَاذِ بْنِ جَبَلٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا عَنْ رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«اتَّقِ اللَّهَ حَيْثُمَا كُنْت، وَأَتْبِعْ السَّيِّئَةَ الْحَسَنَةَ تَمْحُهَا، وَخَالِقْ النَّاسَ بِخُلُقٍ حَسَنٍ».
[قال الترمذي: حديث حسن] - [رواه الترمذي] - [الأربعون النووية: 18]
المزيــد ...
Láti ọdọ Abu Dhari, tii ṣe Jundub ọmọ Junaadah, àti Abu Abdir-Rahman, tii ṣe Mu'ahdh ọmọ Jabal kí Ọlọhun yọnu sí awọn méjèjì, láti ọdọ òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ o máa ba a, o sọ pé:
«Bẹrù Ọlọhun ní ibikibi tí o ba wa, tẹ̀lé ìṣe búburú pẹ̀lú ìṣe rere, yóò pa á rẹ́; máa ba awọn ènìyàn lo pẹlu ìwà daada».
[قال الترمذي: حديث حسن] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [الأربعون النووية - 18]
Annabi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o máa ba npa wa lasẹ nkan mẹta ọtọtọ: Alakọkọ: ìbẹ̀rù Ọlọhun pẹlu pé kí a máa ṣe awọn nkan tí o jẹ ọranyan, àti gbígbé awọn nkan tí o jẹ èèwọ jù silẹ ní gbogbo ààyè àti àsìko àti ìṣesí, ní kọkọ àti ni gbangba, ni gbàá Alaafia àti àdánwò àti bẹ bẹ lọ. Ẹlẹẹkeji: tí o ba bọ sínú àìda kan, yaa ṣe iṣe daada kan lẹyìn rẹ; gẹgẹ bi kí ọ kirun, àti itọrẹ aanu, iṣe daada sí òbí àti iso òkun ẹbi pọ, àti itọrọ aforiji ẹsẹ -tàbí isiwọ kúrò níbi ẹsẹ- àti bẹ bẹ lọ, nitoripe dájúdájú eléyun yiò pàá àìda rẹ. Ẹlẹẹkẹta: Baa awọn ènìyàn lo pẹlu awọn iwā daada, bíi irẹrin musẹ sí wọn tàbí itujuka, àti ise pẹlẹ pẹlu wọn, àti rirọ pẹlu wọn, ati sise daada si wọn àti ikora dúró níbi fífi aburú kan wọn.