عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«دَعُونِي مَا تَرَكْتُكُمْ، إِنَّمَا هَلَكَ مَنْ كَانَ قَبْلَكُمْ بِسُؤَالِهِمْ وَاخْتِلَافِهِمْ عَلَى أَنْبِيَائِهِمْ، فَإِذَا نَهَيْتُكُمْ عَنْ شَيْءٍ فَاجْتَنِبُوهُ، وَإِذَا أَمَرْتُكُمْ بِأَمْرٍ فَأْتُوا مِنْهُ مَا اسْتَطَعْتُمْ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 7288]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Ẹ fi mi sílẹ̀ lópin ìgbà tí mo ba fi yin sílẹ̀, dajudaju nnkan ti o pa awọn ti wọn ṣáájú yin run ni ibeere wọn ati iyapa wọn si awọn anabi wọn, ti mo ba kọ nnkan kan fun yin ẹ jinna si i, ti mo ba pa yin láṣẹ àlámọ̀rí kan ẹ mu u wa de ibi ti ikapa yin ba mọ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7288]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ pe dajudaju awọn idajọ ti Sharia pin si awọn ipin mẹta: Nnkan ti wọn dakẹ lori rẹ, ati awọn nnkan ẹkọ, ati awọn àṣẹ.
Akọkọ: Oun ni nnkan ti ofin dakẹ nipa rẹ: Pe ko si idajọ, ati pe dajudaju ipilẹ nibi awọn nnkan ni aijẹ dandan; Ṣugbọn ni igba aye rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbigbe ibeere ju silẹ nipa nnkan kan ti ko ṣẹlẹ̀ jẹ dandan ni ti ipaya ki ijẹ dandan tabi ṣíṣe ni èèwọ̀ ma sọkalẹ nipa rẹ, dajudaju Ọlọhun fi i kalẹ ni ti ikẹ fun awọn ẹru, Ṣùgbọ́n lẹyin iku rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ibeere ba jẹ láti béèrè nipa idajọ ẹsin, tabi lati kọ eeyan ni nnkan ti wọn n bukaata si ninu àlámọ̀rí ẹsin, o lẹtọọ, bi ko ṣe pe o jẹ nnkan ti wọn pa wa láṣẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ti o ba jẹ ọ̀nà láti béèrè ni tipátipá ni, oun ni a gba lero pẹlu gbigbe ibeere ju silẹ nipa rẹ ninu hadiiisi yìí; ìyẹn ri bẹ́ẹ̀ nitori pe o le ja si iru nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si awọn ọmọ Ísírẹ́lì, ti wọn pa wọn láṣẹ pe ki wọn du màlúù kan, ka ni pe wọn du èyíkéyìí màlúù ni, wọn ti mu àṣẹ naa ṣẹ, ṣùgbọ́n wọn le koko wọn si le koko mọ wọn.
Ikeji: Awọn èèwọ̀; àwọn ni: Nnkan ti wọn maa san ẹni ti o ba gbe e ju silẹ lẹ́san, ti wọn maa fi iya jẹ ẹni ti o ba ṣe e, jijinna si gbogbo rẹ jẹ dandan.
Ẹlẹẹkẹta: Awọn aṣẹ; àwọn naa ni nkan ti wọn maa san ẹni ti o ba ṣe e ni ẹsan, ti wọn o si jẹ ẹni ti o ba fi i silẹ ni iya, nitori naa o jẹ dandan ki a ṣe ninu rẹ èyí tí agbara ba ka.