عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«خَيْرُ يَوْمٍ طَلَعَتْ عَلَيْهِ الشَّمْسُ يَوْمُ الْجُمُعَةِ، فِيهِ خُلِقَ آدَمُ، وَفِيهِ أُدْخِلَ الْجَنَّةَ، وَفِيهِ أُخْرِجَ مِنْهَا، وَلَا تَقُومُ السَّاعَةُ إِلَّا فِي يَوْمِ الْجُمُعَةِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 854]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 854]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju eyi ti o daa julọ ninu ọjọ ti oorun ran ninu rẹ ni ọjọ Jimọ, Ninu awọn iroyin rẹ ti o fi da yatọ ni pe: Dajudaju Ọlọhun ṣẹda Aadam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ninu rẹ, ninu rẹ ni O mu u wọnu alujanna, ninu rẹ ni O mu u jade lati inu rẹ ti O si mu u sọkalẹ sori ilẹ̀, ọjọ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ.