عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بنِ مسعُودٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ:
ذُكِرَ عِنْدَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ رَجُلٌ نَامَ لَيْلَهُ حَتَّى أَصْبَحَ، قَالَ: «ذَاكَ رَجُلٌ بَالَ الشَّيْطَانُ فِي أُذُنَيْهِ، أَوْ قَالَ: فِي أُذُنِهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3270]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mashood - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé:
Wọn sọ nípa ọkunrin kan lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti o sun lati alẹ titi ilẹ fimọ, Anobi sọ pé: "arakunrin naa ni èṣù (Satani) ti tọsi inu eti rẹ méjèejì, tabi o sọ pé: sinu eti rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3270]
Wọn darukọ ọkunrin kan lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti o sun titi ti ilẹ fi mọ ti orun fi yọ ti kò si dide kirun ọranyan, ni Anabi ba sọ pe: oun ni arakunrin kan ti èṣù (Satani) ti tọ sí inu eti rẹ.