عن بريدة بن الحصيب رضي الله عنه أنه قال:
بَكِّرُوا بِصَلَاةِ الْعَصْرِ، فَإِنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: «مَنْ تَرَكَ صَلَاةَ الْعَصْرِ فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 553]
المزيــد ...
Lati ọdọ Buroida ọmọ Al-Husoib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ẹ tete maa ki irun Asr, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 553]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi ki èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ lọ irun Asr lara tayọ asiko rẹ, ati pe ẹni ti o ba ṣe bẹẹ, iṣẹ rẹ ti bajẹ, o si ti lọ lasan.