+ -

عَنْ كَعْبِ بْنِ عُجْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مُعَقِّبَاتٌ لَا يَخِيبُ قَائِلُهُنَّ -أَوْ فَاعِلُهُنَّ- دُبُرَ كُلِّ صَلَاةٍ مَكْتُوبَةٍ، ثَلَاثٌ وَثَلَاثُونَ تَسْبِيحَةً، وَثَلَاثٌ وَثَلَاثُونَ تَحْمِيدَةً، وَأَرْبَعٌ وَثَلَاثُونَ تَكْبِيرَةً».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ka‘bu ọmọ ‘Ujroh - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin».

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo nipa awọn iranti ti ẹni ti o ba n sọ ọ o le mofo ti ko si le kabamọ, bi ko ṣe pe ẹsan awọn gbolohun yii a maa bẹ fun un, wọn o si maa wa lẹyin ara wọn, ti wọn o si tun maa sọ wọn lẹyin irun ọranyan, oun naa ni:
"Subhānallāh" ọgbọn ati mẹta, iyẹn ni fifọ Ọ mọ kuro nibi adinku.
Ati "AlhamduliLlāhi" ni igba ọgbọn ati mẹta, ati pe oun ni ìròyìn Ọlọhun pẹlu pipe papọ mọ ninifẹẹ Rẹ ati gbigbe titobi fun Un.
Ati "Allāhu akbar" ni igba ọgbọn ati mẹẹrin, nitori pe Ọlọhun tobi O si gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe subhānallāh ati alhamduliLlāhi ati Allāhu Akbar, ati pe awọn ni awọn iṣẹ rere to maa wa titi láéláé.