+ -

عَن أَبي مُوْسى الأَشْعريِّ رضي الله عنه قال: قال رسولُ اللهِ صلى اللهُ عليه وسلم:
«مَثَلُ الْمُؤْمِنِ الَّذِي يَقْرَأُ الْقُرْآنَ كَمَثَلِ الْأُتْرُجَّةِ، رِيحُهَا طَيِّبٌ وَطَعْمُهَا طَيِّبٌ، وَمَثَلُ الْمُؤْمِنِ الَّذِي لَا يَقْرَأُ الْقُرْآنَ كَمَثَلِ التَّمْرَةِ، لَا رِيحَ لَهَا وَطَعْمُهَا حُلْوٌ، وَمَثَلُ الْمُنَافِقِ الَّذِي يَقْرَأُ الْقُرْآنَ مَثَلُ الرَّيْحَانَةِ، رِيحُهَا طَيِّبٌ وَطَعْمُهَا مُرٌّ، وَمَثَلُ الْمُنَافِقِ الَّذِي لَا يَقْرَأُ الْقُرْآنَ كَمَثَلِ الْحَنْظَلَةِ، لَيْسَ لَهَا رِيحٌ وَطَعْمُهَا مُرٌّ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5427]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
“Àpèjúwe Mumini ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti oorun rẹ daa, ti itọwo rẹ naa si daa, àpèjúwe mumini ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso dabinu, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ si dùn, àpèjúwe munaafiki ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso rayhaanah, ti oorun rẹ dùn, ti itọwo rẹ si korò, àpèjúwe munaafiki ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso hansọla, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ tún korò".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5427]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ṣe alaye àwọn ìpín awọn eniyan nipa kika Al-Qur’an ati jijẹ anfaani rẹ:
Ìpín akọkọ: Mumini ti n ka Kuraani ti o si n ṣe àǹfààní pẹ̀lú rẹ, o da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti itọwo ati oorun rẹ daa, ti awọ rẹ si daa, ti anfaani rẹ si pọ̀, o n lo nnkan ti o n ka, o si n ṣe awọn ẹru Ọlọhun ni anfaani.
Ìkejì: Mumini ti kii ka Kuraani, o da gẹgẹ bii èso dabinu, itọwo rẹ dun, ko si ni oorun, ọkàn rẹ ko ìgbàgbọ́ sínú, gẹgẹ bi eso dabinu ṣe ko adun sinu nibi itọwo rẹ ati inú rẹ, ati aihan oorun rẹ ti àwọn èèyàn a gbọ́; torí aihan kika rẹ ti awọn eeyan le fi àyà balẹ si gbigbọ rẹ.
Ikẹta: Munaafiki ti n ka Kuraani, o da bii eso rayhaanah, ti oorun rẹ daa ti itọwo rẹ korò, torí igbagbọ ko tun ọkàn rẹ ṣe, ko si lo Kuraani, o wa n ṣe bii mumini loju àwọn èèyàn, oorun rẹ ti o daa jọ kika a, itọwo rẹ ti o korò si jọ iṣe Kèfèrí rẹ.
Ikẹrin: Munaafiki ti kii ka Kuraani, o da bii eso hansọla, ko ni oorun, itọwo rẹ si korò, àìní oorun rẹ jọ aika rẹ, ìkorò itọwo rẹ jọ ìkorò ìṣe Kèfèrí rẹ, ko si igbagbọ ninu rẹ, òde rẹ naa o ṣe anfaani, bi ko ṣe pe o tun n ko inira bani ni.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àlàyé ọla ti n bẹ fun ẹni tí n ka Kuraani ti o si n lò ó.
  2. Ninu ọ̀nà ikọnilẹkọọ ni fifi àpèjúwe lélẹ̀; lati jẹ ki agbọye rẹ o sunmọ.
  3. O yẹ ki musulumi ni ipin kan ninu Kuraani ti o ma maa kà ti o ma maa lọ ti ko nii duro.