عن أبي موسى الأشعري رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«تَعَاهَدُوا هَذَا الْقُرْآنَ، فَوَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَهُوَ أَشَدُّ تَفَلُّتًا مِنَ الْإِبِلِ فِي عُقُلِهَا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 791]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 791]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o wa tẹnu mọ́ ọn pẹ̀lú ìbúra pe Kuraani yára kuro ninu àyà ju rakunmi ti a so lọ, oun naa ni eyi ti a fi okùn dè ni aarin ẹsẹ, ti eeyan ba n ka a nígbà gbogbo, o maa di i mu, ti o ba si tu u sílẹ̀, o maa lọ.