عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«أَلْحِقُوا الفَرَائِضَ بِأَهْلِهَا، فَمَا بَقِيَ فَلِأَوْلَى رَجُلٍ ذَكَرٍ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6737]
المزيــد ...

Láti ọdọ Ibnu Abbas -kí Ọlọhun o yọnu sí awọn méjèjì- láti ọdọ Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ o máa ba a, o s'ọpe:
“Ẹ fi àwọn ìpín ogún (fara’id) fún àwọn tí ó tọ si, oun tí ó bá ṣẹkù lẹ́yìn náà, kó lọ fún ọkùnrin tí ó sunmọ́ (oku) jù lọ (ní ìbátan)".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6737]

Àlàyé

Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o maa ba- n paṣẹ fún àwọn tí ń ṣàkóso ogún pínpín pé kí wọ́n pín (ogun ti oku fi silẹ) fún àwọn tí ó tọ si, ni ìpín ti o ṣe dede ofin (shari'a), gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun ṣe fẹ́. Nítorí náà, a máa fún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ní ipin wọn, tí awọn ìpín naa si jẹ: ìdáméjì ninu ida mẹta ogún, idankan idamẹta, idafa, ìdajì, idamẹrin, ati idamejọ ogún, ohun tí o ba wa sẹku lẹyin naa, a o fún ẹni tí ó sunmọ́ oku jù lọ ninu awọn ọkùnrin, ti wọ́n sì ń pè wọn ní Al-‘asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Hadithi yii jẹ ìpìlẹ lori ilana ogún pínpín.
  2. Ati pé pínpín ogún a máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun (Ahlu Al-fara’id) ní ipin wọn.
  3. Àti pé ohun tí o ba sẹku (ninu ogun) lẹyin igba ti àwọn onípin ba ti gba ipin wọn tan yiò máa jẹ tí awọ̀n Al-Asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).
  4. Títi awọn tí o sunmọ òkú jùlọ síwájú ni tẹle ntẹle, nitori na Al-Aasibu ti o jina -gẹgẹ bí ọmọiya bàbá òkú- ko ni jẹ ogun lopin igba ti Al-Aasibu ti o sunmọ ba wa gẹgẹ bí Bàbá Oku.
  5. Àti pé kòni si ogún kankan fún Al-Aasibu ti awọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ba ti kárí gbogbo ogún tí o wa nlẹ tán, iyẹn nipe tí kò ba sẹku nkankan mọ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (46)
Àlékún