عن أنس بن مالك رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«يَسِّرُوا وَلَا تُعَسِّرُوا، وَبَشِّرُوا وَلَا تُنَفِّرُوا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 69]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 69]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin.
O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.