عن أسامة بن زيد رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَا تَرَكْتُ بَعْدِي فِتْنَةً أَضَرَّ عَلَى الرِّجَالِ مِنَ النِّسَاءِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5096]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Usaamah ọmọ Zayd- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5096]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe oun ko fi àdánwò kan kan silẹ lẹ́yìn oun ti o ni àwọn ọkùnrin lára ju àwọn obìnrin lọ, ti o ba jẹ ọkan ninu awọn araale rẹ ni, o le ṣẹlẹ̀ lati ọdọ rẹ nibi iyapa sharia lati tẹle e, ti o ba si jẹ àjòjì si i, o le ṣẹlẹ̀ pẹlu iropọ mọ́ ọn ati dida wà pẹ̀lú rẹ, ati aburu ti o le ti ibẹ jáde.