+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بنِ عُمرَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُما أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«كُلُّكُمْ رَاعٍ فَمَسْئُولٌ عَنْ رَعِيَّتِهِ، فَالأَمِيرُ الَّذِي عَلَى النَّاسِ رَاعٍ وَهُوَ مَسْئُولٌ عَنْهُمْ، وَالرَّجُلُ رَاعٍ عَلَى أَهْلِ بَيْتِهِ وَهُوَ مَسْئُولٌ عَنْهُمْ، وَالمَرْأَةُ رَاعِيَةٌ عَلَى بَيْتِ بَعْلِهَا وَوَلَدِهِ وَهِيَ مَسْئُولَةٌ عَنْهُمْ، وَالعَبْدُ رَاعٍ عَلَى مَالِ سَيِّدِهِ وَهُوَ مَسْئُولٌ عَنْهُ، أَلاَ فَكُلُّكُمْ رَاعٍ وَكُلُّكُمْ مَسْئُولٌ عَنْ رَعِيَّتِهِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2554]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ 'Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,, adari fun awọn eniyan jẹ adaranjẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ọkunrin ni adaranjẹ lori awọn ara ile rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, obinrin ni adaranjẹ lori ilẹ baale rẹ ati ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ẹru jẹ adaranjẹ lori dukia olowo rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa rẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ́, gbogbo yin ni adaranjẹ ati pe gbogbo yin ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o dajẹ".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2554]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ojúṣe kan jẹ dandan fun gbogbo Musulumi ni awujọ ti o ma maa ṣọ ọ ti o si maa gbe e ru, Imam ati adari jẹ adaranjẹ nibi nnkan ti Ọlọhun fi wọn ṣọ́, sisọ awọn ofin wọn jẹ dandan fun un, ati didaabo bo wọn kuro lọdọ ẹni ti o ba ṣe abosi si wọn, ati gbigbe ogun ti ọta wọn, ati aima ra awọn ẹtọ wọn lare, Ati pe ọkunrin nipa awọn ara ile rẹ jẹ ẹni ti ninawo fun wọn jẹ dandan le e lori, ati biba wọn lo daadaa, ati kikọ wọn nimọ ati kikọ wọn lẹkọọ, Ati obinrin ninu ile ọkọ rẹ jẹ adaranjẹ pẹlu didari ile rẹ daadaa, ati titọ awọn ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe ọmọ ọdọ ti o jẹ ẹrú ati alagbaṣe jẹ adaranjẹ nibi dukia olowo rẹ pẹlu sisọ nnkan ti o n bẹ lọwọ rẹ lati ọdọ rẹ, ati sinsin in, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe gbogbo olúkúlùkù ni adaranjẹ nibi nnkan ti wọn fi ṣọ́, ati pe gbogbo olúkúlùkù ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o n dajẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ojúṣe ninu àwùjọ ti musulumi jẹ gbogboogbo, oníkálukú pẹ̀lú bi o ba ṣe mọ ni ati ikapa rẹ ati ojúṣe rẹ.
  2. Titobi ojúṣe obinrin, ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe iwọ ile ọkọ rẹ ati awọn ojúṣe rẹ si awọn ọmọ rẹ.
Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn