+ -

عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ الْمُقْسِطِينَ عِنْدَ اللهِ عَلَى مَنَابِرَ مِنْ نُورٍ، عَنْ يَمِينِ الرَّحْمَنِ عَزَّ وَجَلَّ، وَكِلْتَا يَدَيْهِ يَمِينٌ، الَّذِينَ يَعْدِلُونَ فِي حُكْمِهِمْ وَأَهْلِيهِمْ وَمَا وَلُوا».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1827]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì, àwọn ti wọn n ṣe deede nibi ìdájọ́ wọn, ati lọ́dọ̀ àwọn ará ilé wọn, ati nibi ohun ti n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1827]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe àwọn ti wọn n dajọ pẹ̀lú deede ati òdodo láàrin àwọn èèyàn ti wọn n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn ati idajọ wọn, ati ara ile wọn, wọ́n maa jókòó lori aga ti o ga ti wọn da latara imọlẹ, láti ṣe apọnle wọn ni ọjọ́ igbende. Ọwọ́ ọ̀tún Ọlọhun ni àwọn minbari yii maa wà, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ méjèèjì.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọlá ti n bẹ fun deede ati ṣiṣenilojukokoro lori rẹ.
  2. Deede kari gbogbo ìjọba ati idajọ láàrin àwọn èèyàn, titi dórí deede laarin awọn ìyàwó, ati awọn ọmọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  3. Ṣíṣe àlàyé ipò àwọn onideede ni ọjọ igbende.
  4. Yiyatọ ipò àwọn onigbagbọ si ara wọn ni ọjọ́ igbende, onikaluku ni ibamu si iṣẹ rẹ ni.
  5. Ọ̀nà ṣiṣenilojukokoro wa ninu awọn ọ̀nà ipepe ti maa n jẹ ki o wu ẹni tí a n pè lati tẹle ti Ọlọhun.