عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«كُلُّ أُمَّتِي يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ إِلَّا مَنْ أَبَى»، قَالُوا: يَا رَسُولَ اللهِ، وَمَنْ يَأْبَى؟ قَالَ: «مَنْ أَطَاعَنِي دَخَلَ الْجَنَّةَ، وَمَنْ عَصَانِي فَقَدْ أَبَى».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 7280]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni o maa kọ̀? O sọ pe: “Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ mi yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá yapa àṣẹ mi ti kọ̀”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7280]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo ìjọ òun ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀!
Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa sọ pé: Ta ni ẹni tí ó máa kọ̀ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun?!
O da wọn lohun pe: Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa wọ alujanna, ṣùgbọ́n ẹni tí o ba yapa ofin sharia ti kọ̀ lati wọ alujanna pẹ̀lú iṣẹ burúkú rẹ.