+ -

عن عبدِ الله بن عمرو رضي الله عنهما قال:
كنتُ أكتبُ كلَّ شيءٍ أسمعُه من رسولِ الله صلَّى الله عليه وسلم أُريدُ حفْظَه، فنهتْني قريشٌ، وقالوا: أتكْتبُ كلَّ شيءٍ تَسمَعُه من رسول الله صلَّى الله عليه وسلم، ورسولُ الله صلَّى الله عليه وسلم بَشَرٌ يتكلَّمُ في الغضَبِ والرِّضا؟ فأمسَكتُ عن الكتاب، فذكرتُ ذلك لرسول الله صلَّى الله عليه وسلم، فأومأ بإصبَعِه إلى فيه، فقال: «اكتُبْ، فوالذي نفسي بيدِه، ما يَخرُجُ منه إلا حقٌّ».

[صحيح] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 3646]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe:
Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – silẹ ni erongba ati de e mọlẹ, ni awọn Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ṣé wa maa kọ gbogbo nkan ti o ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni, ti o si jẹ pe ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko ibinu ati iyọnu? Ni mo ba dawọ duro nibi kikọ, ni mo wa sọ iyẹn fun ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ, ni o wa sọ pe: «Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo».

[O ni alaafia] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 3646]

Àlàyé

AbduLlaah ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si i– sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki n le baa de e mọlẹ pẹlu kikọ, ni awọn ọkunrin kan ninu Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko iyọnu ati ibinu, ti o si le ṣe aṣiṣe, ni mo ba dawọ duro nibi kikọ.
Ni mo ba sọ fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa nkan ti wọn sọ, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ o wa sọ pe: Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo ni eyikeyi ìṣesí ti ko baa jẹ, ati ni asiko iyọnu ati ibinu.
Ati pe Ọba ti ọla Rẹ ga ti sọ nipa Anabi Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe: {Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú * Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i} [An-Najmu 3-4].

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹni ti a sọ kuro nibi aṣisọ ni nibi nkan ti o ba jiṣẹ rẹ lati ọdọ Oluwa rẹ ti O tobi ti O gbọnngbọn, ni asiko ti o ba n yọnu ati igba ti o ba n binu.
  2. Ojukokoro awọn saabe – ki Ọlọhun yọnu si wọn – lori ṣiṣọ sunnah ati mimu un de etiigbọ awọn eeyan.
  3. Lilẹtọọ ibura fun anfaani kan koda lai beere fun ibura, gẹgẹ bii kikanpa mọ alamọri kan.
  4. Kikọ imọ silẹ ninu awọn okunfa to pataki lati ṣọ imọ ni.