عن عَمْرُو بْنُ عَامِرٍ عَنْ أَنَس بن مالك قَالَ:
كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَتَوَضَّأُ عِنْدَ كُلِّ صَلَاةٍ، قُلْتُ: كَيْفَ كُنْتُمْ تَصْنَعُونَ؟ قَالَ: يُجْزِئُ أَحَدَنَا الْوُضُوءُ مَا لَمْ يُحْدِثْ.
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 214]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe:
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa sọ pe: Bawo ni ẹyin ṣe maa n ṣe? O sọ pe: Aluwala ẹyọkan maa n to fun ẹnikẹni ninu wa lopin igba ti ko ba ti dá ẹgbin.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 214]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati ọla.
O si tun lẹtọọ ki o ki ju irun ọranyan ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan lopin igba ti o ba ṣi ni aluwala.