عَنِ ‌ابْنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما قَالَ:
تَوَضَّأَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مَرَّةً مَرَّةً.

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 157]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe:
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe aluwala ni ẹyọkọọkan.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 157]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti o ṣe pe ni awọn igba miran ti o ba ṣe aluwala yio fọ oríkèé kọọkan ninu awọn oríkèé ara rẹ ni ẹẹkan, ti yio fọ oju – ninu rẹ ni yiyọ ẹnu ati fifin imu -, ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji ni ẹẹkan, ati pe eleyii ni odiwọn ti o jẹ dandan.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Eyi ti o jẹ dandan nibi fifọ awọn oríkèé ara ni ifọ ẹẹkan, eyi ti o ba si lekun nkan ti wọn fẹ ni (sunnah).
  2. Ṣiṣe aluwala ni ẹyọkọọkan ni ofin ni awọn igba miran.
  3. Nnkan ti a ṣe lofin nibi pipa ori ni ẹẹkan.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (58)