+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«لَا يَقْبَلُ اللهُ صَلَاةَ أَحَدِكُمْ إِذَا أَحْدَثَ حَتَّى يَتَوَضَّأَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6954]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6954]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ninu awọn majẹmu nini alafia irun ni: Imọra, nitori naa o jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ ki irun ki o ṣe aluwala ti o ba ṣe pe ọkan ninu awọn nkan ti o maa n ba aluwala jẹ ba ṣẹlẹ si i; gẹgẹ bii igbẹ tabi itọ tabi oorun tabi nkan ti o yatọ si i.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Wọn o nii gba irun ẹni ti o ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe imọra pẹlu iwẹ kuro nibi ẹgbin nla ati pẹlu aluwala kuro nibi ẹgbin kekere.
  2. Aluwala oun ni bibu omi ati yiyi i po ninu ẹnu ati titu u jade, lẹyin naa ni fifi eemi rẹ fa omi si inu imu, lẹyin naa ni fifin in jade, lẹyin naa ni fifọ oju ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni fifọ ọwọ mejeeji de igunpa ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni pipa gbogbo ori ni ẹẹkan, lẹyin naa ni fifọ ẹsẹ mejeeji de koko ẹsẹ ni ẹẹmẹta.