+ -

عَن أَبِي أُمَامَةَ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتَ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَخْطُبُ فِي حَجَّةِ الوَدَاعِ فَقَالَ:
«اتَّقُوا اللَّهَ رَبَّكُمْ، وَصَلُّوا خَمْسَكُمْ، وَصُومُوا شَهْرَكُمْ، وَأَدُّوا زَكَاةَ أَمْوَالِكُمْ، وَأَطِيعُوا ذَا أَمْرِكُمْ تَدْخُلُوا جَنَّةَ رَبِّكُمْ».

[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 616]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Umaamah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣe khutubah ni hajj idagbere, o sọ pe:
"Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 616]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe khutubah ni ọjọ 'Arafah, ni hajj idagbere, ni ọdun kẹwàá ninu hijira, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dagbere fun awọn eniyan nibẹ, O pa awọn eniyan patapata láṣẹ lati bẹru Oluwa wọn pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn ẹ̀kọ̀ Rẹ. Pe ki wọn maa ki awọn irun maraarun-un ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọran-anyan ni ọsan ati alẹ. Pe ki wọn maa gba awẹ oṣu Ramadan. Pe ki wọn maa yọ saka awọn dukia fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ki wọn si ma ṣe ahun pẹlu rẹ. Pe ki wọn maa tẹle awọn ti Ọlọhun fi ṣe adari le wọn lori, yàtọ̀ si ibi ṣiṣẹ Ọlọhun, Ẹni ti o ba ṣe awọn nnkan ti a dárúkọ yìí, ẹsan rẹ ni wiwọ alujanna.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn iṣẹ yii wa ninu awọn okunfa wiwọ alujanna.