+ -

عَنْ جَرِيرِِ بْنِ عَبْدِ اللَّهِ رضي الله عنه قَالَ:
بَايَعْتُ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَلَى شَهَادَةِ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ، وَإِقَامِ الصَّلاَةِ، وَإِيتَاءِ الزَّكَاةِ، وَالسَّمْعِ وَالطَّاعَةِ، وَالنُّصْحِ لِكُلِّ مُسْلِمٍ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2157]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2157]

Àlàyé

Saabe Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe oun dunnimọ oun si ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati pipe awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ ọran-anyan ni ọsan ati alẹ, pẹlu awọn majẹmu rẹ ati awọn origun rẹ ati awọn dandan rẹ ati awọn sunnah rẹ, ati lori pipe saka ti a ṣe ni ọran-anyan, oun ni ijọsin ti owo ti o jẹ dandan, ti wọn maa n gba lọwọ awọn ọlọrọ ti wọn si maa n fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ninu awọn alaini ati awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn, ati lori itẹle fun awọn adari, ati iṣiti fun gbogbo Musulumi, ìyẹn pẹlu ṣíṣe ojúkòkòrò láti ṣe e ni anfaani, ati mimu daadaa de ọdọ rẹ, ati titi aburu danu fun un pẹlu ọrọ ati iṣẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki irun kiki ati saka yiyọ, ati pe mejeeji wa ninu awọn origun Isilaamu.
  2. Pataki iṣiti ati ifunra ẹni ni ìmọ̀ràn laaarin awọn Musulumi, titi ti awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- fi ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori rẹ.