+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بِن مَسْعُودٍ رضي الله عنه قَالَ:
سَأَلْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: أَيُّ العَمَلِ أَحَبُّ إِلَى اللَّهِ؟ قَالَ: «الصَّلاَةُ عَلَى وَقْتِهَا»، قَالَ: ثُمَّ أَيٌّ؟ قَالَ: «ثُمَّ بِرُّ الوَالِدَيْنِ» قَالَ: ثُمَّ أَيٌّ؟ قَالَ: «الجِهَادُ فِي سَبِيلِ اللَّهِ» قَالَ: حَدَّثَنِي بِهِنَّ، وَلَوِ اسْتَزَدْتُهُ لَزَادَنِي.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 527]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun" o sọ pe: O sọ wọn fun mi, ti mo ba wa alekun rẹ dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 527]

Àlàyé

Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? O sọ pe: Irun ọran-anyan kiki ni asiko rẹ ti Ọba aṣofin pa aala rẹ, Lẹyin naa, ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji, pẹlu ṣíṣe daadaa si awọn mejeeji, ati mimojuto ẹtọ awọn mejeeji, ati gbigbe ṣiṣẹ awọn mejeeji ju silẹ, Lẹyin naa, jija ogun si oju ọna Ọlọhun, fun gbigbe ọrọ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- soke, ati dida aabo bo ẹsin Isilaamu ati awọn Musulumi, ati fifi awọn ami rẹ han, ìyẹn pẹlu ẹmi ati owo.
Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: O sọ awọn iṣẹ yii fun mi; ti mo ba sọ fun un pe: Lẹyin naa èwo? Dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ini-ọla-ju-ara-wọn-lọ awọn iṣẹ laarin ara wọn wà nibamu si ifẹ Ọlọ́hun fun wọn.
  2. Ìṣe Musulumi lojukokoro lori iko akolekan lori awọn iṣẹ ti wọn dara julọ ati eyi ti o dara tẹle e.
  3. Iyatọ awọn ìdáhùn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa eyi ti o dara julọ ninu awọn iṣẹ wà ni ibamu si yiyatọ awọn eniyan ati awọn isẹsi wọn, ati eyi ti o pọ julọ ni anfaani fun gbogbo ẹni kọọkan ninu wọn.