عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ أَثْقَلَ صَلَاةٍ عَلَى الْمُنَافِقِينَ صَلَاةُ الْعِشَاءِ وَصَلَاةُ الْفَجْرِ، وَلَوْ يَعْلَمُونَ مَا فِيهِمَا لَأَتَوْهُمَا وَلَوْ حَبْوًا، وَلَقَدْ هَمَمْتُ أَنْ آمُرَ بِالصَّلَاةِ فَتُقَامَ، ثُمَّ آمُرَ رَجُلًا فَيُصَلِّيَ بِالنَّاسِ، ثُمَّ أَنْطَلِقَ مَعِي بِرِجَالٍ مَعَهُمْ حُزَمٌ مِنْ حَطَبٍ إِلَى قَوْمٍ لَا يَشْهَدُونَ الصَّلَاةَ، فَأُحَرِّقَ عَلَيْهِمْ بُيُوتَهُمْ بِالنَّارِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 651]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
«Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 651]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ nipa awọn munaafiki ati kikọlẹ wọn nibi wiwa ki irun, agaga julọ irun Ishai ati Asunbaa, ati pe dajudaju ti wọn ba mọ odiwọn ẹsan ati laada ti o wa nibi wiwa ki mejeeji pẹlu janmọọn ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ rirakoro gẹgẹ bi ọmọde ṣe maa n rakoro pẹlu ọwọ ati orunkun.
. Ati pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti pinnu lati paṣẹ pe ki wọn o gbe irun duro, ki o wa fi ọkunrin kan si aaye rẹ lati ṣiwaju awọn eeyan, lẹyin naa ki o wa gbera ti awọn ti wọn gbe idi igi lọwọ si wa pẹlu rẹ, lati lọ ba awọn ọkunrin ti wọn o ki n ki irun janmọọn ninu masalaasi, lẹyin naa ki o wa da’na sun ile wọn; latari ini-agbara ẹṣẹ ti wọn ko si nibi iyẹn, - ṣugbọn ko ṣe e – latari awọn ti wọn wa ninu ile bii awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o mọ nkankan ati awọn to yatọ si wọn ninu awọn ti wọn ni idiwọ (ti wọn ni awijare), awọn ti ko si ẹṣẹ kankan fun wọn.