+ -

عن أبي مالكٍ الأشعريِّ رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«الطُّهُورُ شَطْرُ الْإِيمَانِ، وَالْحَمْدُ لِلهِ تَمْلَأُ الْمِيزَانَ، وَسُبْحَانَ اللهِ وَالْحَمْدُ لِلهِ تَمْلَآنِ -أَوْ تَمْلَأُ- مَا بَيْنَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ، وَالصَّلَاةُ نُورٌ، وَالصَّدَقَةُ بُرْهَانٌ، وَالصَّبْرُ ضِيَاءٌ، وَالْقُرْآنُ حُجَّةٌ لَكَ أَوْ عَلَيْكَ، كُلُّ النَّاسِ يَغْدُو، فَبَايِعٌ نَفْسَهُ فَمُعْتِقُهَا أَوْ مُوبِقُهَا».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 223]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 223]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju imọra ti ìta maa jẹ pẹlu aluwala ati iwẹ, ati pe o jẹ majẹmu fun irun. Ati pe sisọ gbolohun: “ALHAMDULILLAH, o n kun òṣùwọ̀n”, oun ni ẹyin fun Un- mimọ ni fun Un-, ati ìròyìn rẹ pẹlu ìròyìn pipe, wọn maa wọn ọn ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, o maa waa kún òṣùwọ̀n iṣẹ. Ati pe sisọ gbolohun: “Subhaanallah ati Alhamdulillah” oun ni ṣíṣe afọmọ Rẹ kuro nibi gbogbo adinku ati riroyin Rẹ pẹlu pipe ti o pe ti o tọ si titobi Rẹ pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi, yoo kun nnkan ti o wa laaarin sanmọ ati ilẹ. Ati pe “irun jẹ imọlẹ” fun ẹru ni ọkan rẹ, ati ni oju rẹ, ati ninu sàréè rẹ, ati nibi igbedide rẹ. Ati pe “Saara ṣíṣe jẹ awijare” ati ẹri lori ododo igbagbọ olugbagbọ, ati iyapa rẹ si ṣọbẹ-ṣelu ti kii ṣe saara; nitori pe ko ni igbagbọ si ohun ti wọn ṣe adehun rẹ lórí saara ṣíṣe. Ati pe “Suuru ṣíṣe jẹ imọlẹ” -oun ni kiko ẹ̀mí ro nibi ìgbónára ati ibinu- imọlẹ kan ni ti igbona ati jijo nkan maa n waye pẹlu rẹ, gẹgẹ bii imọlẹ oòrùn; nitori pe nnkan ti o nira ni, o si n bukaata si jija ẹ̀mí naa logun ati dide e kuro nibi nnkan ti o n fẹ; ẹni ti o ba ni i ko nii yẹ ko nii gbo ni ẹni ti yoo maa mọna ti yoo si maa tẹsiwaju lori nnkan ti o tọna. Oun ni ṣíṣe suuru lori itẹle ti Ọlọhun, ati kuro nibi ẹṣẹ, ati suuru ṣíṣe lori awọn ajalu ati awọn oniran-anran àwọn nnkan ti eeyan korira ni ayé. Ati pe “Kuraani jẹ awijare fun ẹ” pẹlu kika a ati ṣíṣe ìṣẹ́ pẹlu rẹ, tabi “awijare tako ẹ” pẹlu gbigbe e ju silẹ lai fi ṣe iṣẹ́ tabi kika a. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju gbogbo eniyan n gbiyanju ti wọn n fọnka ti wọn si n dide lati oju orun wọn ti wọn n jade lati inu awọn ile wọn tori awọn ìṣẹ́ wọn ni oríṣiríṣi, O wa ninu wọn ẹni ti o n duro deedee lori itẹle ti Ọlọhun ti yoo tu ẹ̀mí rẹ kuro ninu ina, o si wa ninu wọn ẹni ti yoo yẹ kuro nibi ìyẹn ti yoo si ko si inu awọn ẹṣẹ ti yoo si pa a run pẹlu wiwọ ina.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Imọra pin si meji: Imọra ti ita, o maa waye pẹlu aluwala ati iwẹ, ati imọra ti inú, o maa waye pẹlu imu Ọlọhun ni Ọkan ati igbagbọ ati iṣẹ oloore.
  2. Pataki mímú ojú tó irun ati pe o jẹ imọlẹ fun erusin Ọlọhun ni aye ati ọjọ igbedide.
  3. Saara ṣíṣe jẹ ẹri lori ododo igbagbọ.
  4. Pataki ṣíṣe iṣẹ pẹlu Kuraani ati gbigba a lododo lati le jẹ ẹri fun ẹ ti ko nii tako ẹ.
  5. Ẹmi ti o ko ba ko airoju ba a pẹlu itẹle yoo ko airoju ba ẹ pẹlu ẹṣẹ.
  6. Gbogbo eniyan dandan ni fun un pe ko ṣiṣẹ; ninu pe ki o bọ okun lọrun ara rẹ pẹlu itẹle tabi ki o ko iparun ba a pẹlu ẹṣẹ.
  7. Suuru ṣíṣe n bukaata si atẹmọra ati wiwa ẹsan ti ilekoko si n bẹ nibẹ.