+ -

عن المقدام بن معدِيْكَرِب رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«أَلَا هَلْ عَسَى رَجُلٌ يَبْلُغُهُ الْحَدِيثُ عَنِّي وَهُوَ مُتَّكِئٌ عَلَى أَرِيكَتِهِ فَيَقُولُ: بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ كِتَابُ اللهِ، فَمَا وَجَدْنَا فِيهِ حَلَالًا اسْتَحْلَلْنَاهُ، وَمَا وَجَدْنَا فِيهِ حَرَامًا حَرَّمْنَاهُ، وَإِنَّ مَا حَرَّمَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَمَا حَرَّمَ اللهُ».

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه] - [سنن الترمذي: 2664]
المزيــد ...

Lati ọdọ Al-Miqdam Bin Ma’dikarib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ".

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2664]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe asiko kan ti sunmọ ti iran kan ninu awọn eniyan o jẹ ẹni ti o jokoo nibẹ, ọkan ninu wọn maa rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ti hadisi lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa de eti igbọ rẹ, yoo waa maa sọ pe: Nnkan ti o maa ṣe ìyàtọ̀ laaarin wa ati laaarin yin nibi awọn alamọri ni Kuraani Alapọn-ọnle, o si ti to wa, nnkan ti a ba ba nibẹ ninu nnkan ẹtọ a maa ṣiṣẹ pẹlu rẹ, nnkan ti a ba si ba nibẹ ninu nnkan eewọ a maa jina si i. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan ti o ṣe ni eewọ tabi kọ kuro nibẹ ninu sunnah rẹ, ninu idajọ o da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ ninu iwe Rẹ; nitori pe oun ni o n jiṣẹ Oluwa rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Gbigbe sunnah tobi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n gbe Kuraani tobi ti wọn si maa n ṣe iṣẹ́ pẹlu rẹ.
  2. Itẹle Òjíṣẹ́ ni itẹle ti Ọlọhun, iyapa rẹ naa si jẹ ìyapa Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  3. Ẹri to fẹsẹrinlẹ ni Sunnah ati fifesi fun awọn ti wọn kọ Sunnah tabi ti wọn tako o.
  4. Ẹni ti o ba gunri kuro nibi sunnah ti o so pe Kuraani nìkan ti to, o ti gunri kuro nibi mejeeji lapapọ, o si tun jẹ opurọ nibi apemọra itẹle Kuraani rẹ.
  5. Ninu awọn ẹri ijẹ-anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni àwọn nǹkan tí ó sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, ti o si ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí.