عَنْ أَنَسٍ رضي الله عنه قَالَ:
جَاءَ رَجُلٌ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، مَا تَرَكْتُ حَاجَّةً وَلَا دَاجَّةً إِلَّا قَدْ أَتَيْتُ، قَالَ: «أَلَيْسَ تَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ؟» ثَلَاثَ مَرَّاتٍ. قَالَ: نَعَمْ، قَالَ: «فَإِنَّ ذَلِكَ يَأْتِي عَلَى ذَلِكَ».
[صحيح] - [رواه أبو يعلى والطبراني والضياء المقدسي] - [الأحاديث المختارة للضياء المقدسي: 1773]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? Ni ẹẹmẹta. O sọ pe: bẹẹni, Anabi sọ pe Dajudaju ìyẹn maa pa àwọn ẹṣẹ yẹn rẹ.
[O ni alaafia] - [Abu Yahlaa ati Tọbarọọniy ati Ad-Diyaau Al-Makdisiy ni wọn gba a wa] - [Àwọn hadiisi ti a ṣẹsa fun Ad-Diyaahul Makdisiy - 1773]
Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju mo ti da gbogbo ẹṣẹ, ti mi ko fi ẹṣẹ kekere tabi ńlá kalẹ afi ki n ti ṣe e, njẹ wọn maa forí jin mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? O paara rẹ ni ẹẹmẹta, O da a lohun pe: Bẹẹni mo n jẹrii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun un ati pipa awọn aburu rẹ̀ rẹ́, ati pe ironupiwada maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.