عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَنَّهُ قَالَ:
«سَيَكُونُ فِي آخِرِ أُمَّتِي أُنَاسٌ يُحَدِّثُونَكُمْ مَا لَمْ تَسْمَعُوا أَنْتُمْ وَلَا آبَاؤُكُمْ، فَإِيَّاكُمْ وَإِيَّاهُمْ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 6]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira, lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 6]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn eniyan kan maa han ni igbẹyin ìjọ rẹ ti wọn maa maa da adapa-irọ, ti wọn maa maa sọ nnkan ti ẹnikẹni ko sọ ṣíwájú wọn, ti wọn maa maa sọrọ pẹlu awọn hadiisi irọ ati agbelẹrọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pa wa láṣẹ lati jina si wọn ki a si ma jokoo pẹlu wọn, ki a si ma tẹti si awọn hadiisi wọn; ki hadiisi ti wọn hun yii ma baa duro ninu awọn ẹ̀mí, ki a ma baa kagara kuro nibi lila kuro nibẹ.