+ -

عن العِرْباضِ بن ساريةَ رضي الله عنه قال:
قام فينا رسول الله صلى الله عليه وسلم ذات يوم، فوَعَظَنا مَوعظةً بليغةً وَجِلتْ منها القلوبُ، وذَرَفتْ منها العيونُ، فقيل: يا رسول الله، وعظتَنَا موعظةَ مُودِّعٍ فاعهد إلينا بعهد. فقال: «عليكم بتقوى الله، والسمع والطاعة، وإن عبدًا حبشيًّا، وسترون من بعدي اختلافًا شديدًا، فعليكم بسنتي وسنة الخلفاء الراشدين المهديين، عَضُّوا عليها بالنواجِذ، وإياكم والأمور المحدثات، فإن كل بدعة ضلالة».

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن ابن ماجه: 42]
المزيــد ...

Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waasu kan ti o de ògòńgó fun wa ti awọn ọkan ń gbọn riri latara rẹ, ti awọn oju n dami latara rẹ, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o ṣe waasu idagbere fun wa, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun wa. O sọ pe: "Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin, ẹ di wọn mu pẹlu eyin ọgan, ẹ ṣọra fún awọn adadaalẹ, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni".

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Ibnu Maajah - 42]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe waasu kan ti o de ogongo fun awọn saabe, ti awọn ọkan gbọn ti awọn oju dami latara rẹ, Wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun o da gẹgẹ bii waasu idagbere fun nnkan ti wọn ri ninu wiwọnu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi waasu náà, wọn wa beere fun àsọtẹ́lẹ̀ ki wọn le gba a mu lẹyin rẹ, O sọ pe: Mo n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yin pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, Ati gbigbọ ati itẹle, o n túmọ̀ si: Fun awọn adari, ko da ki ẹru jẹ adari fun yin, o n túmọ̀ si ki ẹni ti o kere julọ ninu ẹda di adari le yin lori, ẹ ko gbọdọ kọ ìyẹn, ki ẹ si tẹle e, ni ti ipaya dídá fitina sílẹ̀, dajudaju ẹni ti o ba ṣẹmi ninu yin maa pada ri iyapa ti o pọ, Lẹyin naa o ṣàlàyé ọna àbáyọ fun wọn kuro nibi iyapa yìí, ìyẹn pẹlu gbigba sunnah rẹ mu ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a fi ọna mọ wọn lẹyin rẹ, Abu Bakr, ati Umar ọmọ Khattaab, ati Uthman ọmọ 'Affan, ati Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ-, ati gbigba a mu pẹlu ẹyin ọgan, o n túmọ̀ si- awọn ẹyin ẹgbẹ ti o kẹ́yìn-: O n túmọ̀ ẹyin ọgan yẹn si didunnimọ sunnah daada ati didirọmọ ọn, O ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi awọn alamọri ti a da wọn silẹ sinu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki didirọmọ sunnah ati itẹle ẹ.
  2. Akolekan si awọn waasu ati rirọ awọn ọkan.
  3. Pipaṣẹ pẹlu itẹle awọn arole ẹni imọna ti a fi wọn mọna mẹrẹẹrin lẹyin rẹ, awọn ni Abu Bakr, ati Umar, ati Uthman, ati Aliy- ki Ọlọhun yọnu si wọn-.
  4. Kikọ kuro nibi adadaalẹ ninu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.
  5. Gbigbọ ati itẹle fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn olugbagbọ ni ọna ti o yàtọ̀ si oju ọna ẹṣẹ.
  6. Pataki ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ni gbogbo asiko ati iṣesi.
  7. Iyapa jẹ nnkan ti o n ṣẹlẹ̀ ninu ijọ yìí, nigba ti o ba ṣẹlẹ̀, ṣiṣẹripada si sunnah ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ti awọn arole ẹni imọna maa jẹ dandan.
Àlékún