+ -

عَنْ ‌أَنَسِ بْنِ مَالِكٍ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ افْتَقَدَ ثَابِتَ بْنَ قَيْسٍ، فَقَالَ رَجُلٌ: يَا رَسُولَ اللهِ، أَنَا أَعْلَمُ لَكَ عِلْمَهُ، فَأَتَاهُ فَوَجَدَهُ جَالِسًا فِي بَيْتِهِ، مُنَكِّسًا رَأْسَهُ، فَقَالَ: مَا شَأْنُكَ؟ فَقَالَ شَرٌّ، كَانَ يَرْفَعُ صَوْتَهُ فَوْقَ صَوْتِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُ، وَهُوَ مِنْ أَهْلِ النَّارِ، فَأَتَى الرَّجُلُ فَأَخْبَرَهُ أَنَّهُ قَالَ كَذَا وَكَذَا، فَرَجَعَ الْمَرَّةَ الْآخِرَةَ بِبِشَارَةٍ عَظِيمَةٍ، فَقَالَ: «اذْهَبْ إِلَيْهِ فَقُلْ لَهُ: إِنَّكَ لَسْتَ مِنْ أَهْلِ النَّارِ، وَلَكِنْ مِنْ أَهْلِ الْجَنَّةِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3613]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik – ki Ọlọhun yọnu si i:
Dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi, ni arakunrin kan wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, maa mu iro rẹ wa fun ọ, ni o ba wa ba a ti o si ba a ni ẹni ti o jokoo si inu ile rẹ, ti o da ori rẹ kodo, ni o wa sọ pe: Ki lo ṣe ẹ? O sọ pe: Aburu ni, o maa n gbe ohun rẹ soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, nitori naa iṣẹ rẹ ti bajẹ, ati pe oun ti wa ninu awọn ọmọ ina, ni arakunrin naa ba pada wa ti o si fun un niroo wí pé o sọ bai bai, o tun wa pada wa ni igba ikẹhin pẹlu iro idunnu ti o tobi, nigba naa ni o wa sọ pe: «Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3613]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi – ki Ọlọhun yọnu si i – o wa beere nipa rẹ, ni arakunrin kan wa sọ pe: Maa mu iro rẹ wa fun ọ, ati idi ti o fi sa, ni o wa lọ si ọdọ rẹ ti o si ba a ni ẹni ti n banujẹ ti o si da ori kodo ninu ile rẹ, ni o wa bi i leere pe: Ki lo ṣe ọ? Ni Thābit wa sọ fun un nkan ti o ṣe e ninu aburu; latari pe oun maa n gbe ohun oun soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti Ọlọhun si ti ṣe adun fun ẹni ti o ba ṣe iyẹn pẹlu bibajẹ iṣẹ rẹ, ati pe ninu awọn ọmọ ina ni yio wa.
Ni arakunrin naa wa pada si ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si fun un niroo nipa iyẹn, ni Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa pa a laṣẹ ki o ṣẹri pada si ọdọ Thābit ki o si fun un ni iro idunnu wipe dajudaju ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna, ati pe lilọ soke ohun rẹ iṣẹda rẹ ni, ati pe o jẹ agbẹnusọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si tun jẹ agbẹnusọ fun awọn An-soor.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye ọla Thābit ọmọ Qaysi – ki Ọlọhun yọnu si i– ati pe ninu ọmọ alujanna lo wa.
  2. Akolekan Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu awọn saabe ati bíbéèrè rẹ nípa wọn.
  3. Ibẹru awọn saabe – ki Ọlọhun yọnu si wọn – ati ipaya wọn nipa pe ki awọn iṣẹ wọn o ma bajẹ.
  4. Jijẹ dandan lilo ẹkọ nibi biba a – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọrọ ni igba aye rẹ, ati rirẹ ohun nilẹ nigba ti a ba n gbọ sunnah rẹ lẹyin iku rẹ.