عَنِ الْبَرَاءِ رضي الله عنه:
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَنَّهُ قَالَ فِي الْأَنْصَارِ: «لَا يُحِبُّهُمْ إِلَّا مُؤْمِنٌ، وَلَا يُبْغِضُهُمْ إِلَّا مُنَافِقٌ، مَنْ أَحَبَّهُمْ أَحَبَّهُ اللهُ وَمَنْ أَبْغَضَهُمْ أَبْغَضَهُ اللهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 75]
المزيــد ...
Lati ọdọ Al-Barrohu- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 75]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju nini ifẹ awọn Ansar ninu awọn ara Madina, jẹ àmì lori pipe igbagbọ; eleyii rí bẹ́ẹ̀ nitori gbigba iwaju wọn nibi aranṣe Isilaamu ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati gbigbiyanju nibi gbigba awọn Musulumi sile, ati nina awọn dukia wọn ati ẹmi wọn si oju ọna Ọlọhun, ati pe kikorira wọn jẹ ami lori ṣiṣe sobẹ-ṣelu. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ awọn Ansar, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ.