+ -

عَنْ أَنَسِ بْنِ مَالِكٍ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا عَدْوَى، وَلَا طِيَرَةَ، وَيُعْجِبُنِي الْفَأْلُ» قَالَ قِيلَ: وَمَا الْفَأْلُ؟ قَالَ: «الْكَلِمَةُ الطَّيِّبَةُ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa".

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akoran ti èèyàn asiko aimọkan ni adisọkan rẹ pe dajudaju aisan maa n ṣi kuro fun ara rẹ bọ si ara ẹlomiran láìṣe pẹlu kadara Ọlọhun jẹ ibajẹ, Ati pe ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu jẹ ibajẹ, oun ni ifuramọ aburu lati ara èyíkéyìí nnkan ti a gbọ́ lo jẹ ni tabi ti a ri, ninu awọn ẹyẹ tabi awọn ẹranko tabi awọn oni ailera tabi awọn onka tabi awọn ọjọ tabi eyi ti o yàtọ̀ si wọn, Wọn dárúkọ awọn ẹyẹ nitori pe o jẹ eyi ti o gbajumọ lọdọ awọn ara asiko aimọkan, ati pe ipilẹ rẹ ni titu ẹyẹ silẹ nigba ti a ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii irin-ajo tabi owo tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, ti o ba fo lọ si ẹgbẹ ọtun, ó maa furamọ daadaa, o si maa ba nnkan ti o fẹ lọ, ti o ba fo lọ si ẹgbẹ òsì, o maa furamọ aburu, o si maa koraro kuro nibi nnkan ti o fẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọrọ daadaa maa n wu òun, oun ni nnkan ti o maa n ṣẹlẹ̀ si ọmọniyan bii ayọ̀ ati idunnu ninu ọrọ daadaa ti o n gbọ́, ti o si maa mu ro ero daadaa pẹlu Olúwa rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, oun ni pe ko si ẹni ti o le mu oore wa afi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu danu afi Ọlọhun.
  2. Kikọ kuro nibi ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe oun ni nnkan ti wọn maa n fura mọ aburu latara rẹ, ti o si maa n ṣẹri ẹni kúrò nibi iṣẹ.
  3. Ifuramọ idunnu ko ki n ṣe ara ifi ẹyẹ furamọ daadaa tabi aburu ti a kọ kuro nibẹ, bi ko ṣe pe o wa ninu nini ero daadaa pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  4. Gbogbo nnkan maa n ṣẹlẹ̀ pẹlu kadara Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.