عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رَضِيَ اللهُ عَنْهُمَا:
أَنَّ نَاسًا مِنْ أَهْلِ الشِّرْكِ، كَانُوا قَدْ قَتَلُوا وَأَكْثَرُوا، وَزَنَوْا وَأَكْثَرُوا، فَأَتَوْا مُحَمَّدًا صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالُوا: إِنَّ الَّذِي تَقُولُ وَتَدْعُو إِلَيْهِ لَحَسَنٌ، لَوْ تُخْبِرُنَا أَنَّ لِمَا عَمِلْنَا كَفَّارَةً، فَنَزَلَ {وَالَّذِينَ لا يَدْعُونَ مَعَ اللهِ إِلَهًا آخَرَ وَلا يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللهُ إِلا بِالْحَقِّ وَلا يَزْنُونَ}[الفرقان: 68]، وَنَزَلَت: {قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَى أَنْفُسِهِمْ لا تَقْنَطُوا مِنْ رَحْمَةِ اللهِ} [الزمر: 53].
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4810]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji:
Dajudaju awọn eeyan kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn mu orogun mọ Ọlọhun), ti wọn si pa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn tun ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa ba Muhammad – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni wọn wa sọ fun un pe: Dajudaju nkan ti o n sọ ti o si n pepe si, nkan ti o daa ni, ti o ba fun wa niroo pe aforijin n bẹ fun nkan ti a ṣe, nigba naa ni o sọkalẹ pe {(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā}[Al-Furqān: 68], o tun sọkalẹ pe: {Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu}[Az-Zumar: 53].
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4810]
Awọn ọkunrin kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn n mu nkan mii mọ Ọlọhun) wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, wọn si ti pa eeyan lọpọlọpọ ti wọn ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa sọ fun Anabi pe: Dajudaju nkan ti o n pepe si ninu Isilaamu ati awọn ẹkọ rẹ nkan ti o daa ni, ṣugbọn bawo ni ọrọ wa o ṣe wa jẹ pẹlu nkan ti a ti ko si ni imu orogun mọ Ọlọhun ati awọn ẹṣẹ nlanla, njẹ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ wa fun un bi?
Nitori naa ni aaya mejeeji yii ba sọkalẹ, nibi ti Ọlọhun ti gba ironupiwada lọwọ awọn eeyan pẹlu pipọ awọn ẹṣẹ wọn ati titobi rẹ, ati pe bi ko ba ṣe titori iyẹn wọn o ba si wa lori ṣiṣe keferi wọn ati àgbéré wọn, wọn ba si ma wọ inu ẹsin yii.