+ -

عَنِ ‌ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما:
أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ خَطَبَ النَّاسَ يَوْمَ فَتْحِ مَكَّةَ، فَقَالَ: «يَا أَيُّهَا النَّاسُ، إِنَّ اللهَ قَدْ أَذْهَبَ عَنْكُمْ عُبِّيَّةَ الْجَاهِلِيَّةِ وَتَعَاظُمَهَا بِآبَائِهَا، فَالنَّاسُ رَجُلَانِ: بَرٌّ تَقِيٌّ كَرِيمٌ عَلَى اللهِ، وَفَاجِرٌ شَقِيٌّ هَيِّنٌ عَلَى اللهِ، وَالنَّاسُ بَنُو آدَمَ، وَخَلَقَ اللهُ آدَمَ مِنْ تُرَابٍ، قَالَ اللهُ: {يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ} [الحجرات: 13]».

[صحيح] - [رواه الترمذي وابن حبان]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ ‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji:
Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ba awọn eeyan sọrọ ni ọjọ ti wọn ṣi Makkah, ni o wa sọ pe: «Mo pe ẹyin eeyan, dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ṣiṣe iyanran wọn pẹlu awọn baba wọn, nitori naa meji ni awọn eeyan: eniire olupaya alapọn-ọnle lọdọ Ọlọhun, ati onibajẹ oloriibu ẹni yẹpẹrẹ lọdọ Ọlọhun, awọn eeyan, ọmọ Anabi Aadam ni wọn, ti Ọlọhun si da Aadam lati ibi erupẹ, Ọlọhun sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán} [Al-Hujrāt: 13]».

O ni alaafia - Tirmiziy ni o gba a wa

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ba awọn eeyan sọrọ ni ọjọ ti wọn ṣi Makkah, o wa sọ pe: Mo pe ẹyin eeyan dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ijọra-ẹni-loju rẹ, ati fifi awọn baba ẹni ṣe iyanran, ati pe awọn eeyan iran meji ni wọn:
Ninu ki o jẹ Mumini eniire olupaya Ọlọhun olutẹle aṣẹ ti n jọ́sìn fun Ọlọhun, eleyii alapọn-ọnle ni lọdọ Ọlọhun, koda ki o ma jẹ ẹni ti o ni ipo ati iran lọdọ awọn eeyan.
Tabi ki o jẹ keferi onibajẹ oloriibu, eleyii ẹni yẹpẹrẹ ti ko ni asunsi ni lọdọ Ọlọhun, ti ko si ja mọ nkankan, koda ko jẹ abiyi ti o ni ipo ati ọla.
Ati pe gbogbo eeyan pata ọmọ Anabi Aadam ni wọn, ti Ọlọhun si da Aadam lati ibi erupẹ, nitori naa ko lẹtọọ fun ẹni ti ipilẹ rẹ jẹ erupẹ ki o ṣe igberaga ati ijọra-ẹni-loju, ati pe nkan ti o fi idi iyẹn mulẹ ni gbolohun Ọlọhun ti O tobi ti O gbọnngbọn to sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán} [Al-Hujrāt: 13].

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikọ kuro nibi ṣiṣe iyanran pẹlu iran ati ipo.