عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«كُلُّ سُلاَمَى مِنَ النَّاسِ عَلَيْهِ صَدَقَةٌ، كُلَّ يَوْمٍ تَطْلُعُ فِيهِ الشَّمْسُ يَعْدِلُ بَيْنَ الِاثْنَيْنِ صَدَقَةٌ، وَيُعِينُ الرَّجُلَ عَلَى دَابَّتِهِ فَيَحْمِلُ عَلَيْهَا أَوْ يَرْفَعُ عَلَيْهَا مَتَاعَهُ صَدَقَةٌ، وَالكَلِمَةُ الطَّيِّبَةُ صَدَقَةٌ، وَكُلُّ خُطْوَةٍ يَخْطُوهَا إِلَى الصَّلاَةِ صَدَقَةٌ، وَيُمِيطُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ صَدَقَةٌ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2989]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ, gbogbo ọjọ ti oorun ba ti n yọ ti o ba n ṣe deede laarin eeyan meji saara ni, ati pe ki o ran ẹnikan lọwọ l'ori nkan ọ̀gùn rẹ, boya ki o gbe e gun un tabi ki o gbe ẹru rẹ fun un lori rẹ saara ni, ati pe ọrọ daadaa saara ni, ati gbogbo igbesẹ ti o ba n gbe lọ sí ibi irun saara ni, ki o si tun maa mu nkan ti o le ṣe eeyan ni ṣuta kuro l'ọna saara ni»
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2989]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan l'ori gbogbo musulumi ti o ni iwọ ni ọrùn ni ojoojumọ pẹlu onka gbogbo ibi tí àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara rẹ lati maa ṣe saara, ti yio ṣe e fun Ọlọhun lati fi dupẹ alaafia, ati pe o ṣe awọn ibi ipadepọ àwọn eegun rẹ ni nkan ti o jẹ ki o rọrun fun un lati ka a kò ati lati nà án, Ati pe dajudaju saara yẹn yio maa jẹ ṣiṣe pẹlu gbogbo iṣẹ daadaa patapata, ko si mọ nibi ifunni ni owo nikan, ninu rẹ naa sì ni: Deede rẹ ati atunse rẹ laarin awọn onija meji saara ni, Ati pe saara n bẹ nibi iranlọwọ rẹ fun ẹni ti o kagara nibi nkan ọ̀gùn rẹ ti waa wa gbe e gun un tabi ki o na ọwọ ẹru rẹ fún un, Ati pe ọrọ ti o daa bii iranti ati adua ati salamọ ati eyi ti o yatọ si i saara ni, Ati pe gbogbo igbesẹ kọọkan ti o ba n gbe lọ s'ibi irun saara ni, Ati pe mimu nkan ti o le ṣeni ni ṣuta kuro l'ọna saara ni.