+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه:
أَنَّ رَجُلًا قَالَ لِلنَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: أَوْصِنِي، قَالَ: «لَا تَغْضَبْ» فَرَدَّدَ مِرَارًا قَالَ: «لَا تَغْضَبْ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6116]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Arákùnrin kan sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi, o sọ pé: “Ma ṣe maa binu”, o wa pààrà rẹ ni ọpọlọpọ ìgbà, o tun sọ pé: “Ma ṣe maa bínú”.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6116]

Àlàyé

Ọ̀kan ninu awọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o tọka òun si nǹkan kan tí o maa ṣe e ni anfaani, o wa pa a láṣẹ ki o ma maa bínú, itumọ ìyẹn ni pe ki o jìnnà si awọn okùnfà ti o le mu u binu, ki o si ko ara rẹ ni ìjánu ti ìbínú bá ṣẹlẹ̀, ki o ma tẹ síwájú nibi ibinu rẹ pẹlu pípa, tàbí lílù, tabi èébú, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Arákùnrin naa paara wíwá àsọtẹ́lẹ̀ naa ni ọpọlọpọ ìgbà, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko sọ fun un nibi àsọtẹ́lẹ̀ naa ju pe “ma ṣe maa binu”.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikilọ kuro nibi ìbínú ati awọn okùnfà rẹ; tori pe oun ni o ko gbogbo aburu sinu, ṣiṣọra kuro nibẹ ni o ko gbogbo oore sínú.
  2. Ibinu nítorí Ọlọhun, gẹgẹ bii ibinu nígbà tí wọ́n bá rú òfin Ọlọhun, eyi wa lara ibinu ti o dára.
  3. Àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tí a bá nílò rẹ̀ títí tí olùgbọ́ yóò fi mọ̀ nípa rẹ̀ tí yóò sì mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀.
  4. Ọla ti n bẹ fun wíwá àsọtẹ́lẹ̀ lati ọdọ onimimọ.