عن أبي سعيد الخدري رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«لَا ضَرَرَ وَلَا ضِرَارَ، مَنْ ضَارَّ ضَرَّهُ اللَّهُ، وَمَنْ شَاقَّ شَقَّ اللَّهُ عَلَيْهِ».
[صحيح بشواهده] - [رواه الدارقطني] - [سنن الدارقطني: 3079]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Saheed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”.
[O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ] - [Daarukutniy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Daarukutniy - 3079]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dandan ni ki eeyan ti aburu dànù kuro lọ́dọ̀ ara ẹni ati kúrò lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, iru inira yòówù ko ri ki o jẹ, ko ni ẹtọ fun ẹnikẹ́ni ki o fi suta kan ara rẹ tabi ẹlòmíràn láìsí iyatọ.
Ko si ni ẹtọ fun un ki o fi oró yaró; tori pe a kìí mu inira kúrò pẹ̀lú ìnira ayafi ti a ba fẹ gba ẹsan láìní kọjá ààlà.
Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé àdéhùn ìyà ìpalára fun ẹni tí ba n ko ìpalára ba àwọn èèyàn, ati ìnira fun ẹni tí ba n ko ìnira ba àwọn èèyàn.