عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِذَا وَجَدَ أَحَدُكُمْ فِي بَطْنِهِ شَيْئًا، فَأَشْكَلَ عَلَيْهِ أَخَرَجَ مِنْهُ شَيْءٌ أَمْ لَا، فَلَا يَخْرُجَنَّ مِنَ الْمَسْجِدِ حَتَّى يَسْمَعَ صَوْتًا، أَوْ يَجِدَ رِيحًا».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 362]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
«Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 362]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ti nkankan ba n ru ninu iku ẹni ti n kirun, ti ko wa mọ boya nkan jade tabi nkankan o jade? Ko gbọdọ kuro ni ori irun, ko si gbọdọ ja a lati lọ tun aluwala ṣe, titi ti yio fi ri bibẹ ẹgbin ni aridaju eleyii ti o le ba aluwala jẹ; pẹlu pe ki o gbọ didun iso, tabi ki o gbọ oorun; tori pe dajudaju nkan ti a ti mọ amọdaju rẹ ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe oun ti mọ amọdaju imọra, ti ẹgbin si jẹ nkan ti n ṣe iyemeji ninu rẹ.