Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn hadiisi

Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe aluwala ni ẹyọkọọkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu