عن عثمان بن عفان رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 245]
المزيــد ...

Lati ọdọ Uthman ọmọ Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 245]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala pẹlu ṣíṣe àkíyèsí awọn sunna aluwala ati awọn ẹkọ rẹ, iyẹn maa wa ninu awọn okunfa pipa awọn ẹṣẹ rẹ ati pipa àṣìṣe rẹ, titi awọn ẹṣẹ rẹ yoo fi jade labẹ awọn èékánná ọwọ rẹ mejeeji ati ti ẹsẹ rẹ méjèèjì.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣisẹnilojukokoro lori ìní akolekan kikọ aluwala ati sunnah rẹ ati awọn ẹkọ rẹ, ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu ìyẹn.
  2. Ọla ti o n bẹ fun aluwala, ati pe o jẹ ipa ẹṣẹ keekeeke rẹ, sugbọn awọn ẹṣẹ ńlá, ironupiwada jẹ dandan lati pa wọn rẹ.
  3. Majẹmu jijade awọn àṣìṣe ni pipe aluwala ati ṣíṣe e laisi alebu kankan gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ṣàlàyé rẹ.
  4. Pipa ẹṣẹ rẹ ninu hadisi yii jẹ nnkan ti a de pẹlu ijina si awọn ẹṣẹ ńlá ati ironupiwada kuro nibẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé: (Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá tí A kọ̀ fun yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fun yín) (An-Nisa: 31).
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)