عَنْ جَابِرٍ رضي الله عنه قال: أَخْبَرَنِي عُمَرُ بْنُ الْخَطَّابِ:
أَنَّ رَجُلًا تَوَضَّأَ فَتَرَكَ مَوْضِعَ ظُفُرٍ عَلَى قَدَمِهِ فَأَبْصَرَهُ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَ: «ارْجِعْ فَأَحْسِنْ وُضُوءَكَ» فَرَجَعَ، ثُمَّ صَلَّى.
[صحيح بشواهده] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 243]
المزيــد ...
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Umar ọmọ Khatob fun mi niroo pe:
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun.
[O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 243]
Umar - ki Ọlọhun yọnu si i - funni niroo pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ri arakunrin kan ti o ti pari aluwala rẹ, ti o wa fi deedee eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ ti ko mu omi aluwala de ibẹ, Ni o wa sọ lẹni ti o na'ka si aaye aṣeeto yẹn: Pada ki o lọ ṣe aluwala rẹ daadaa ki o si pe e ki o si tun fun oríkèé kọọkan ni ẹtọ rẹ ninu omi, Ni arakunrin naa ba pada ti o sì lọ pe aluwala rẹ lẹyin naa ni o kirun.