عن عائشة رضي الله عنها قالت:
كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَذْكُرُ اللهَ عَلَى كُلِّ أَحْيَانِهِ.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 373]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe:
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 373]
‘Āisha iya gbogbo mu’mini – ki Ọlọhun yọnu si i – n sọ pe dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti ojukokoro rẹ pọ gidi gan lori riranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati pe dajudaju o jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba ati aaye ati ìṣesí.