+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«صِنْفَانِ مِنْ أَهْلِ النَّارِ لَمْ أَرَهُمَا، قَوْمٌ مَعَهُمْ سِيَاطٌ كَأَذْنَابِ الْبَقَرِ يَضْرِبُونَ بِهَا النَّاسَ، وَنِسَاءٌ كَاسِيَاتٌ عَارِيَاتٌ مُمِيلَاتٌ مَائِلَاتٌ، رُؤُوسُهُنَّ كَأَسْنِمَةِ الْبُخْتِ الْمَائِلَةِ، لَا يَدْخُلْنَ الْجَنَّةَ، وَلَا يَجِدْنَ رِيحَهَا، وَإِنَّ رِيحَهَا لَيُوجَدُ مِنْ مَسِيرَةِ كَذَا وَكَذَا».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
Awọn iran eniyan meji kan wa ninu ara ina ni wọn, mi ko ri wọn, ijọ kan ni ti awọn ọrẹ n bẹ pẹlu wọn ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maluu ti wọn maa n fi i na awọn eniyan, ati awọn obinrin kan wọn maa wọ aṣọ wọn si maa wa ni ihoho, ti wọn maa n mu ẹlòmíràn yẹ gẹrẹ, ti awọn gan ti yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, awọn ori wọn da gẹgẹ bii ike ẹyin màlúù ti o n yẹ, wọn ko nii wọ alujanna, wọn ko si nii gbọ́ oorun rẹ, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn ti maa n ri i lati irin bayii bayii ".

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣekilọ kuro nibi awọn iran eniyan meji kan ninu awọn ara ina, ko ri wọn, wọn ko si si ni igba aye rẹ, sugbọn wọn maa wa lẹyin rẹ:
Iran akọkọ: Awọn ijọ kan ti awọn ọrẹ ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maalu ti wọn gun n bẹ lọwọ wọn, wọn maa n fi i na awọn eniyan, awọn ni awọn ọlọpaa ati awọn ti wọn n kun àwọn alabosi lọ́wọ́, àwọn ti wọn maa n na awọn eniyan lọna ailẹtọọ.
Ati pe iran ikeji ni: Awọn obinrin kan ti wọn ti bọ aṣọ iparamọ ati itiju eyi ti wọn sábà maa n ṣẹda obinrin lori rẹ.
Iroyin wọn ni: Wọn maa wọ aṣọ lódodo, wọn maa wa ni ihoho ni ìtumọ̀; nitori pe wọn wọ aṣọ ti o fẹlẹ ti o n ṣe iroyin ara, wọn si bo apakan ninu ara wọn, ti wọn ṣi apakan rẹ kalẹ; ni ti afihan ẹwà, Ti wọn maa n yi awọn ọkan awọn ọkunrin sọ́dọ̀ wọn pẹlu aṣọ wọn ati ìrìn akọ wọn, ti wọn maa n yẹ awọn ejika wọn, ti wọn maa n yi awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn lọ sibi iyẹgẹrẹ ati iyipada ti awọn ko si, Ninu awọn iroyin wọn ni pé: Awọn ori wọn da gẹgẹ bii ike ẹyin rakunmi ti o tẹ, wọ́n maa n jẹ ki orí wọn tobi pẹ̀lú wiwe aṣọ mọ́rí ati ohun ti o jọ ọ. Ati pe afiwe pẹlu ike ẹyin ràkúnmí rí bẹ́ẹ̀ fun lilọ soke irun wọn ati awọn irun-dídì wọn sórí wọn, ati lílọ́ rẹ pẹlu nnkan ti wọn fi dì í titi o fi maa tẹ̀ si ẹgbẹ kan ni ori gẹgẹ bii ike maalu ṣe maa n tẹ si ẹgbẹ kan. Ẹni ti o ba wa pẹlu awọn iroyin yii, a jẹ pe adehun iya ti o le koko yii n bẹ lara wọn pẹlu pe ki wọn ma wọ alujanna ki wọn si ma gbọ́ oorun rẹ ki wọn si ma sunmọ ọn, ati pe oorun alujanna wọn maa n gbọ́ ọ lati ọna ti o jinna.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe nina awọn eniyan leewọ ati ifiya jẹ wọn laisi ẹṣẹ ti wọn da.
  2. Ṣíṣe ikunlọwọ awọn alabosi leewọ lori ṣíṣe abosi wọn.
  3. Ṣíṣe ikilọ fun awọn obinrin nipa ṣíṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ wọn ati ṣiṣi wọn silẹ ati wiwọ aṣọ ti o fun ati eyi ti èèyàn maa rí ohun ti n bẹ lábẹ́ rẹ ti o maa ṣe iroyin ihoho tabi ki o ṣe afihan rẹ.
  4. Ṣíṣe obinrin lojukokoro si itẹle awọn àṣẹ Ọlọhun, ati ijina si nnkan ti o le bi I ninu ti yio si mu u lẹtọọ si iya ẹlẹta-elero ti gbere ni ọrun.
  5. Hadiisi naa wa ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, nigba ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn àlámọ̀rí ti kọkọ ti ko i tii ṣẹlẹ̀, ti o si ṣẹlẹ̀ bi o ṣe sọ.