عَن أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا يَنْظُرُ الرَّجُلُ إِلَى عَوْرَةِ الرَّجُلِ، وَلَا الْمَرْأَةُ إِلَى عَوْرَةِ الْمَرْأَةِ، وَلَا يُفْضِي الرَّجُلُ إِلَى الرَّجُلِ فِي ثَوْبٍ وَاحِدٍ، وَلَا تُفْضِي الْمَرْأَةُ إِلَى الْمَرْأَةِ فِي الثَّوْبِ الْوَاحِدِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 338]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho ọkunrin, obinrin naa o si gbọdọ maa wo ihoho obinrin, ọkunrin o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu ọkunrin ninu asọ kan, obinrin naa o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu obinrin ninu asọ kan».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 338]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ ki ọkunrin o maa wo ihoho ọkunrin, tabi ki obinrin o maa wo ihoho obinrin.
Ati pe nkan ti n jẹ ‘Aorah ni: Gbogbo nkan ti wọn maa n tiju latara rẹ ti o ba hàn (nkan ti wọn o ki n fẹ ki o han), ati pe ihoho ọkunrin ni nkan ti o wa laarin idodo rẹ ati orunkun rẹ, Ati pe gbogbo ara obinrin pata ni ihoho fun awọn ọkunrin ajoji, ṣugbọn fun awọn obinrin ati awọn eleewọ rẹ, o le fi han nkan ti o saaba maa n han nigba ti o ba n ṣiṣẹ ni inu ile.
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun kọ kuro nibi ki ọkùnrin ati ọkùnrin o wa ni ihoho ninu asọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan, ati nibi ki obinrin ati obinrin o wa ni ihoho ninu aṣọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan; nítorí pé ìyẹn le maa fa ki ọkọọkan ninu wọn o maa fi ọwọ pa ihoho ẹnìkejì rẹ, ati pe fifi ọwọ kan an (ihoho) nkan ti wọn kọ ni gẹgẹ bii wiwo o naa ni, koda kikọ rẹ (fifi ọwọ pa ihoho) tun le jù; latari pe ìyẹn le tini lọ sibi awọn ibajẹ ti o tobi.