عن ابن عمر رضي الله عنهما:
أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ نَهَى عَنِ الْقَزَعِ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5921]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ ‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -:
Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ nkan ti n jẹ al-Qaza‘ (ki èèyàn fá orí apakan ki o dá apakan sí).

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5921]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ fifa apakan irun ori ati fifi apakan silẹ.
Ati pe kikọ naa ko gbogbo ọmọde ọkunrin ati agbalagba ọkunrin sinu, ṣugbọn ọmọbinrin ko tọ fun un ki o fa irun ori rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Nini akolekan ofin Isilāmu si irisi ọmọnìyàn.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)