+ -

عن عائشة رضي الله عنها قالت:
سَأَلَ أُنَاسٌ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَنِ الْكُهَّانِ، فَقَالَ لَهُمْ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لَيْسُوا بِشَيْءٍ» قَالُوا: يَا رَسُولَ اللهِ، فَإِنَّهُمْ يُحَدِّثُونَ أَحْيَانًا بِالشَّيْءِ يَكُونُ حَقًّا، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «تِلْكَ الْكَلِمَةُ مِنَ الْحَقِّ يَخْطَفُهَا الْجِنِّيُّ فَيَقُرُّهَا فِي أُذُنِ وَلِيِّهِ قَرَّ الدَّجَاجَةِ، فَيَخْلِطُونَ فِيهَا أَكْثَرَ مِنْ مِائَةِ كَذْبَةٍ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6213]
المزيــد ...

Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe:
Awọn eeyan kan bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn adagbigba, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ fun wọn pe: «Wọn o jẹ nkankan» wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju wọn maa n sọ awọn nkan ni igba miran ti yio si jẹ ododo, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ pe: «Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6213]

Àlàyé

Wọn bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn ti wọn maa n sọ nipa awọn kọkọ ti yio ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju, ni o wa sọ pe: Ẹ ma bikita pẹlu wọn, Ẹ si ma di ọrọ wọn mu, alamọri wọn o si gbọdọ pataki si yin.
Ni wọn wa sọ pe: Dajudaju ọrọ wọn maa n ṣe deedee nkan ti n ṣẹlẹ ni igba miran, gẹgẹ bii ti wọn ba sọ nipa iṣẹlẹ alamọri kọkọ kan ni oṣu bayii ni ọjọ bayii, ti yio si ṣẹlẹ ni ibamu si ọrọ wọn.
Ni o wa sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe: Dajudaju awọn alujannu maa n ji awọn iroyin sanmọ gbọ, nigba naa ni wọn yio wa sọkalẹ wa ba awọn aayo wọn ninu awọn adagbigba ti wọn o si fun wọn ni iro nkan ti wọn gbọ, lẹ́yìn naa ni adagbigba o fi irọ ọgọrun-un kun eyi ti o gbọ lati sanmọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikọ kuro nibi gbigba awọn adagbigba ni olododo, ati pe dajudaju nkan ti wọn n sọ irọ ati ahunsọ ọrọ ni, koda ki o jẹ ododo ni awọn igba miran.
  2. Wọn sọ sanmọ kuro lọwọ awọn eṣu pẹlu gbigbe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – dide, kuro nibi mimaa gbọ nkankan ninu imisi tabi ohun ti o yatọ si i, ayaafi eyi ti o ba ji ọrọ gbọ ti o si la lọwọ ògúnná.
  3. Awọn alujannu maa n mu awọn aayo ninu awọn eeyan.