عن أنس رضي الله عنه قال:
كُنَّا عِنْدَ عُمَرَ فَقَالَ: «نُهِينَا عَنِ التَّكَلُّفِ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 7293]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe:
A wa ni ọdọ ‘Umar, o wa sọ pe: «Wọn kọ fun wa kuro nibi ifipaṣe-nnkan»

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7293]

Àlàyé

‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si i– n sọ wipe dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ fun wọn kuro nibi imaa ṣe nkan ti ìnira wa nibẹ lai ni bukaata si i, yala o jẹ ọrọ ni abi iṣe.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ninu ifipaṣe-nnkan ti wọn kọ ni: Apọju ibeere, tabi ki o la nkan ti ko ni imọ nipa rẹ bo ara rẹ lọrun, tabi ki o le nibi alamọri ti Ọlọhun fi igbalaaye si i.
  2. O tọ fun Musulumi ki o jẹ ki ẹ̀lẹ̀ mọ́ òun lára, ati ki o má maa fi agídí sọ̀rọ̀ tabi ṣiṣẹ́: Nibi jíjẹ rẹ, ati mimu rẹ, ati awọn ọrọ rẹ, ati gbogbo ìṣesí rẹ.
  3. Isilaamu ẹsin irọrun ni.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)