عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«حُجِبَتِ النَّارُ بِالشَّهَوَاتِ، وَحُجِبَتِ الْجَنَّةُ بِالْمَكَارِهِ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6487]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6487]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé dajudaju awọn nkan tí ẹ̀mí eniyan n fẹ́ ni o wa ní ayika Iná ọ̀run, gẹgẹ bii ṣiṣe awọn nkan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ tabi ikudiẹ-kaato nibi awọn ọranyan; Nitori naa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ifẹẹnu rẹ̀ nibi ìyẹn, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Ina ọ̀run, àti pé dajudaju àwọn nkan tí ẹmi eniyan koriira rẹ̀ ni o wa ní ayika Alujanna; gẹgẹ bii ṣíṣe àwọn nkan tí Ọlọhun pa wá láṣẹ rẹ̀ déédé ati gbigbe àwọn nkan eewọ jù sílẹ̀ àti ṣíṣe sùúrù lori wọn, tí eniyan bá wá tiraka, tí ó sì gbiyanju pẹ̀lú ẹmi ara rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Alujanna.