عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ وَعَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنهما عَنِ النَّبِيِّ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«مَا يُصِيبُ الْمُسْلِمَ مِنْ نَصَبٍ وَلَا وَصَبٍ وَلَا هَمٍّ وَلَا حُزْنٍ وَلَا أَذًى وَلَا غَمٍّ حَتَّى الشَّوْكَةِ يُشَاكُهَا إِلَّا كَفَّرَ اللهُ بِهَا مِنْ خَطَايَاهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5641]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy ati lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5641]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí Mùsùlùmí, bii aisan ati ironu ati ibanujẹ ati ajalu ati ile koko ati ipaya ati ebi- koda ki o jẹ ẹgun ni o gun un ti o wa n ko inira ba a-, ìyẹn maa jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ ati awọn aṣiṣe rẹ.