+ -

عَنْ طَلْحَةَ بْنِ عُبَيْدِ اللهِ رضي الله عنه قَالَ:
جَاءَ رَجُلٌ إِلَى رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مِنْ أَهْلِ نَجْدٍ ثَائِرُ الرَّأْسِ، نَسْمَعُ دَوِيَّ صَوْتِهِ، وَلَا نَفْقَهُ مَا يَقُولُ حَتَّى دَنَا مِنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَإِذَا هُوَ يَسْأَلُ عَنِ الْإِسْلَامِ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «خَمْسُ صَلَوَاتٍ فِي الْيَوْمِ وَاللَّيْلَةِ» فَقَالَ: هَلْ عَلَيَّ غَيْرُهُنَّ؟ قَالَ: «لَا، إِلَّا أَنْ تَطَّوَّعَ، وَصِيَامُ شَهْرِ رَمَضَانَ»، فَقَالَ: هَلْ عَلَيَّ غَيْرُهُ؟ فَقَالَ: «لَا، إِلَّا أَنْ تَطَّوَّعَ»، وَذَكَرَ لَهُ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ الزَّكَاةَ، فَقَالَ: هَلْ عَلَيَّ غَيْرُهَا؟ قَالَ: «لَا، إِلَّا أَنْ تَطَّوَّعَ»، قَالَ: فَأَدْبَرَ الرَّجُلُ، وَهُوَ يَقُولُ: وَاللهِ، لَا أَزِيدُ عَلَى هَذَا، وَلَا أَنْقُصُ مِنْهُ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَفْلَحَ إِنْ صَدَقَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 11]
المزيــد ...

Lati ọdọ Tolha ọmọ 'Ubaidullah - ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Arákùnrin kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn ara Najd, ti irun ori rẹ ri wúruwùru ti ohun rẹ n lọ sókè ti a o si gbọ́ ohun ti n sọ yé, titi ti o fi sunmọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba n beere nipa Isilaamu, ni ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a – wa sọ pé: “Irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́”, o wa sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan míì tun jẹ dandan le mi lórí yàtọ̀ si i? O sọ pe: “Rara, àfi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ, ati aawẹ oṣù Ramadan”, o sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan mii tún jẹ́ dandan fún mi yàtọ̀ sí i? O sọ pe: “Rara, afi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ”, ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa dárúkọ sàká fun un, o sọ pe: Njẹ omiran lẹyin wọn jẹ dandan fun mi? O sọ pe: “Rara, afi ki o ṣe aṣegbọrẹ”, o sọ pe: Ni arakunrin naa yi ẹsẹ pada, o wa n sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko nii lekun lori eyi, mi ko nii dinkun ninu rẹ, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: ”O ti jere ti o ba sọ ododo”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 11]

Àlàyé

Arakunrin kan ninu awọn ara Najd wa sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti irun rẹ ri wuruwuru, ti ohun rẹ lọ sókè, ti wọn ko gbọ nnkan ti o n sọ ye, titi o fi sunmọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si beere nipa awọn ọran-anyan Isilaamu?
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ pẹlu irun, ti o si sọ fun un pe dajudaju Ọlọhun ṣe irun marun-un ni ọran-anyan le e lori ni gbogbo ọ̀sán ati oru.
O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn irun yàtọ̀ si awọn marun-un yii?
O sọ pe: Rara, afi ti o ba ki nafila lati ṣe aṣegbọrẹ.
Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ninu nnkan ti Ọlọhun tun ṣe e ni dandan le ẹ lori ni awẹ oṣu Ramadan.
O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awẹ yàtọ̀ si awẹ Ramadan?
O sọ pe: Rara, afi ti o ba gba aawẹ fun aṣegbọrẹ.
Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ saka fun un.
Arakunrin naa sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn saara lẹyin saka ọran-anyan?
O sọ pe: Rara, a fi ti o ba ṣe aṣegbọrẹ.
Lẹyin igba ti arakunrin naa gbọ́ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa awọn ọran-anyan yìí, o pẹyin da, o si búra pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe oun maa dunni mọ́ ọn laisi alekun tabi adinku, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ lẹyin ìyẹn pé: Ti arakunrin naa ba sọ ododo lori nnkan ti o bura le lori dajudaju o maa wa ninu awọn olujere.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Rirọ Sharia ti Isilaamu ati ṣíṣe irọrun rẹ fun awọn ti a la iwọ̀ Ọlọhun bọ lọrun.
  2. Didara ibalopọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun arakunrin yìí, o ṣe e ni irọrun fun un lati sunmọ ọn ati lati béèrè lọwọ rẹ.
  3. Bibẹrẹ ipepe soju ọna Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu eyi ti o pataki julọ lẹ́yìn náà ni o wa n kan eyi ti o ba tun pàtàkì tẹle e.
  4. Isilaamu jẹ adisọkan ati iṣẹ, iṣẹ kan ko lee ṣe anfaani laisi igbagbọ, igbagbọ kan o si lee ṣe anfaani laisi iṣẹ.
  5. Pataki awọn iṣẹ yii, ati pe wọn wa ninu origun Isilaamu.
  6. Irun jimọh ti wọnu awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ dandan; nitori pe o jẹ ijirọ fun irun Zuhr ni ọjọ jimọh fun ẹni ti o ba jẹ dandan fun.
  7. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ lati kọ́ ọ ni ẹkọ pẹlu eyi ti o kanpa julọ ninu awọn ọran-anyan Isilaamu, oun ni awọn origun rẹ lẹyin ijẹrii mejeeji; nitori pe o jẹ Musulumi, ko dárúkọ hajj; nirori pe ko i tii di ọranyan ni igba naa, tabi ki àsìkò rẹ o ma i tii to.
  8. Ọmọniyan ti o duro lori nnkan ti o jẹ dandan nikan ninu ofin dajudaju o ti jẹ olujere, ṣùgbọ́n eyi ko túmọ̀ si pe wọn ko ṣe ni sunnah fun un lati mu aṣegbọrẹ wá; nitori pe aṣegbọrẹ, ọran-anyan maa n pe tan pẹlu rẹ ni ọjọ igbedide.